Suratu Al-Ahzab, aaya 57

33:57

إِنَّ ٱلَّذِينَ يُؤۡذُونَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ لَعَنَهُمُ ٱللَّهُ فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِ وَأَعَدَّ لَهُمۡ عَذَابٗا مُّهِينٗا ٥٧

Innal-ladhīna yu'dhūnallāha warasūlahū la'anahumullāhu fid-dunyā wal-ākhirati wa a'adda lahum 'adhābam muhīnā

Dájúdájú àwọn tó ń fi ìnira kan Allāhu1 àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, Allāhu ti ṣẹ́bi lé wọn nílé ayé àti ní ọ̀run. Ó sì ti pèsè ìyà tó ń yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ dè wọ́n.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ọ̀nà tí ẹ̀dá ń gbà fi ìnira kan Allāhu - Ọba tí ìnira kì í kàn - nìwọ̀nyí; àìgbàgbọ́ nínú Allāhu, ìṣẹbọ sí Allāhu, ìṣọ̀bẹ-ṣèlu nínú ẹ̀sìn Rẹ̀, ṣíṣe àfitì ìyàwó àti ọmọ bíbí tì sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, pípa irọ́ mọ́ Ọn àti bíbú ìgbà, yíya àwòrán n̄ǹkan ẹlẹ́mìí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Kíyè sí i, fífi ìnira kan Allāhu, Ọbá tí kò sí ìnira fún, kò ní ìtúmọ̀ kan tayọ pé ẹ̀dá ń wá ìnira ọ̀run fún ẹ̀mí ara rẹ̀.