Ẹ̀kọ́ 2 nínú 2
Ta ni àwọn ànábì Ìsìlámù?
Láti inú Al-Qur'ān
قُولُوٓاْ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ وَمَآ أُنزِلَ إِلَيۡنَا وَمَآ أُنزِلَ إِلَىٰٓ إِبۡرَٰهِـۧمَ وَإِسۡمَٰعِيلَ وَإِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَ وَٱلۡأَسۡبَاطِ وَمَآ أُوتِيَ مُوسَىٰ وَعِيسَىٰ وَمَآ أُوتِيَ ٱلنَّبِيُّونَ مِن رَّبِّهِمۡ لَا نُفَرِّقُ بَيۡنَ أَحَدٖ مِّنۡهُمۡ وَنَحۡنُ لَهُۥ مُسۡلِمُونَ ﴿١٣٦﴾
Ẹ sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ya‘ƙūb. (A gbàgbọ́ nínú) ohun tí wọ́n fún (àwọn Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā, àti ohun tí wọ́n fún àwọn Ànábì (yòókù) láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un.”
وَلَقَدۡ بَعَثۡنَا فِي كُلِّ أُمَّةٖ رَّسُولًا أَنِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ وَٱجۡتَنِبُواْ ٱلطَّٰغُوتَۖ فَمِنۡهُم مَّنۡ هَدَى ٱللَّهُ وَمِنۡهُم مَّنۡ حَقَّتۡ عَلَيۡهِ ٱلضَّلَٰلَةُۚ فَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَٱنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُكَذِّبِينَ ﴿٣٦﴾
Dájúdájú A ti gbé Òjíṣẹ́ dìde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan (láti jíṣẹ́) pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì jìnnà sí àwọn òrìṣà.” Nítorí náà, ó wà nínú wọn, ẹni tí Allāhu tọ́ sí ọ̀nà. Ó sì wà nínú wọn, ẹni tí ìṣìnà kò lé lórí. Nítorí náà, ẹ rìn kiri lórí ilẹ̀, kí ẹ sì wòye sí bí àtubọ̀tán àwọn tó pé àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́ ṣe rí?
۞ إِنَّآ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ كَمَآ أَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ نُوحٖ وَٱلنَّبِيِّـۧنَ مِنۢ بَعۡدِهِۦۚ وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰٓ إِبۡرَٰهِيمَ وَإِسۡمَٰعِيلَ وَإِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَ وَٱلۡأَسۡبَاطِ وَعِيسَىٰ وَأَيُّوبَ وَيُونُسَ وَهَٰرُونَ وَسُلَيۡمَٰنَۚ وَءَاتَيۡنَا دَاوُۥدَ زَبُورٗا ﴿١٦٣﴾ وَرُسُلٗا قَدۡ قَصَصۡنَٰهُمۡ عَلَيۡكَ مِن قَبۡلُ وَرُسُلٗا لَّمۡ نَقۡصُصۡهُمۡ عَلَيۡكَۚ وَكَلَّمَ ٱللَّهُ مُوسَىٰ تَكۡلِيمٗا ﴿١٦٤﴾ رُّسُلٗا مُّبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَ لِئَلَّا يَكُونَ لِلنَّاسِ عَلَى ٱللَّهِ حُجَّةُۢ بَعۡدَ ٱلرُّسُلِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمٗا ﴿١٦٥﴾
Dájúdájú Àwa (fi ìmísí) ránṣẹ́ sí ọ gẹ́gẹ́ bí A ṣe fi ránṣẹ́ sí (Ànábì) Nūh àti àwọn Ànábì (mìíràn) lẹ́yìn rẹ̀. A fi ìmísí ránṣẹ́ sí (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ (rẹ̀), àti (Ànábì) ‘Īsā, ’Ayyūb, Yūnus, Hārūn àti Sulaemọ̄n. A sì fún (Ànábì) Dāwūd ní Zabūr. Àti àwọn Òjíṣẹ́ kan tí A ti sọ ìtàn wọn fún ọ ṣíwájú pẹ̀lú àwọn Òjíṣẹ́ kan tí A kò sọ ìtàn wọn fún ọ. Allāhu sì bá (Ànábì) Mūsā sọ̀rọ̀ tààrà. (A ṣe wọ́n ní) Òjíṣẹ́, oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀ nítorí kí àwíjàre má lè wà fún àwọn ènìyàn lọ́dọ̀ Allāhu lẹ́yìn (tí) àwọn Òjíṣẹ́ (ti jíṣẹ́). Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Ìrìn-àjò ti parí
Ẹ kú iṣẹ́!
Ohun tí àwọn Mùsùlùmí gbàgbọ́
Ìrìn-àjò 1 nínú 6 ti parí
Bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò tó kànBí a ṣe ń kírun