Suratu Az-Zukhruf, aaya 59

43:59

إِنۡ هُوَ إِلَّا عَبۡدٌ أَنۡعَمۡنَا عَلَيۡهِ وَجَعَلۡنَٰهُ مَثَلٗا لِّبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ ٥٩

In huwa illā 'abdun an'amnā 'alayhi waja'alnāhu mathalal libanī isrā'īl

Kí ni òun bí kò ṣe ẹrúsìn kan tí A ṣe ìdẹ̀ra fún. A sì ṣe é ní àpẹ̀ẹrẹ rere fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl.1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Nígbà tí Allāhu - Ọba tó ga jùlọ - fi iná wíwọ̀ rínlẹ̀ fún àwọn òrìṣà àti àwọn abọ̀rìṣà wọn, ìyẹn nínú sūrah al-’Ambiyā’; 21:98-100, àwọn abọ̀rìṣà náà bá mú ọ̀rọ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - wá gẹ́gẹ́ bí àpẹ̀ẹrẹ òrìṣà àkúnlẹ̀bọ tó máa wọná. Allāhu sì ṣàfọ̀mọ́ ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - fúnra Rẹ̀ pé kò sọra rẹ̀ d’òòṣà, àmọ́ àwọn tí wọ́n sọ ọ́ d’òòṣà nìkan ló máa wọná.