Suratu At-Tawbah, aaya 108

9:108

لَا تَقُمۡ فِيهِ أَبَدٗاۚ لَّمَسۡجِدٌ أُسِّسَ عَلَى ٱلتَّقۡوَىٰ مِنۡ أَوَّلِ يَوۡمٍ أَحَقُّ أَن تَقُومَ فِيهِۚ فِيهِ رِجَالٞ يُحِبُّونَ أَن يَتَطَهَّرُواْۚ وَٱللَّهُ يُحِبُّ ٱلۡمُطَّهِّرِينَ ١٠٨

Lā taqum fīhi abadal lamasjidun ussisa 'alat-taqwā min awwali yawmin ahaqqu an taqūma fīhi fīhi rijālun yuhibbūna an yatatahharū wallāhu yuhibbul-muttahhirīn

Má ṣe dúró (kírun) nínú rẹ̀ láéláé.1 Dájúdájú mọ́sálásí tí wọ́n bá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí ìbẹ̀rù Allāhu láti ọjọ́ àkọ́kọ́ lo lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ pé kí o dúró (kírun) nínú rẹ̀. Àwọn ènìyàn tó nífẹ̀ẹ́ láti máa ṣe ìmọ́ra wà nínú rẹ̀. Allāhu sì fẹ́ràn àwọn olùṣèmọ́ra.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Kíyè sí i! Gbólóhùn yìí “Má ṣe dúró (kírun) nínú rẹ̀ láéláé.” àti āyah 107 ló ń ṣe é ní èèwọ̀ fún àwa mùsùlùmí onisunnah láti kírun nínú àwọn mọ́sálásí àwọn mùsùlùmí onibidiah pẹ̀lú májẹ̀mu pé tí ó bá jẹ́ pé wọ́n fi mọ́sálásí náà sọrí bid‘ah wọn. Irú àwọn mọ́sálásí tí èyí kàn ni mọ́sálásí Ahmadiyyah àti Zāwiyah àwọn oníwírìdí Tijāniyah, Ƙọ̄diriyyah àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.