Suratu Al-Baqarah, aaya 122

2:122

يَٰبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَتِيَ ٱلَّتِيٓ أَنۡعَمۡتُ عَلَيۡكُمۡ وَأَنِّي فَضَّلۡتُكُمۡ عَلَى ٱلۡعَٰلَمِينَ ١٢٢

Yābanī isrā'īladhkurū ni'matiyal-latī an'amtu 'alaykum wa annī faddaltukum 'alal-'ālamīn

Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, ẹ rántí ìkẹ́ Mi, èyí tí Mo ṣe fún yín. Dájúdájú Èmi tún ṣoore àjùlọ fún yín lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiyín).1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Èyí rí bẹ́ẹ̀ fún wí pé, òǹkà àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu (‘aleehim sọlāt wa salām) pọ̀ púpọ̀ nínú ìran ọmọ ’Isrọ̄’īl ju àwọn ìran ẹ̀dá yòókù lọ, àmọ́ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl náà ni ìran tó ṣàì gbàgbọ́ jùlọ.