Suratu Al-Balad, aaya 2

90:2

وَأَنتَ حِلُّۢ بِهَٰذَا ٱلۡبَلَدِ ٢

Wa anta hillu bihādhal-balad

Ìwọ sì ní ẹ̀tọ́ sí ìlú yìí (láti jagun nínú rẹ̀).1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ẹ̀tọ́ tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fún Ànábì Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni kíkógun ja ìlú Mọkkah lásìkò ogun Ìṣí Mọkkah “Fat-hu Mọkkah”. Ṣíwájú àsìkò yìí àti lẹ́yìn rẹ̀, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ẹnikẹ́ni mọ́ láti jagun nínú ìlú Mọkkah alápọ̀n-ọ́nlé.