Suratu Al-An'am, aaya 20

6:20

ٱلَّذِينَ ءَاتَيۡنَٰهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ يَعۡرِفُونَهُۥ كَمَا يَعۡرِفُونَ أَبۡنَآءَهُمُۘ ٱلَّذِينَ خَسِرُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ فَهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ ٢٠

Alladhīna ātaynāhumul-kitāba ya'rifūnahū kamā ya'rifūna abnā'ahumul-ladhīna khasirū anfusahum fahum lā yu'minūn

Àwọn tí A fún ní Tírà, wọ́n mọ̀ ọ́n gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe mọ àwọn ọmọ wọn. Àwọn tó ṣe ẹ̀mí wọn lófò (sínú àìgbàgbọ́), wọn kò sí níí gbàgbọ́.1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Gbólóhùn yìí “Àwọn tí A fún ní Tírà, wọ́n mọ̀ ọ́n” ń túmọ̀ sí pé, àwọn tó nímọ̀ nípa Taorāt àti ’Injīl mọ̀ pé nínú tírà méjèèjì, ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọ́hun Ẹlẹ́dàá àti pé Òjíṣẹ́ tí wọ́n ń retí ni Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, àmọ́ wọ́n daṣọ bo òtítọ́ mọ́lẹ̀. Ìdí nìyí tí āyah 21 fi pè wọ́n ní alábòsí.